Bẹrẹ Irin-ajo Rẹ
OMO YORUBA RONU
Ajogunba Rẹ Ni Ede ati Owe wa!
"Rántí ọmọ ẹni tí ìwọ ń ṣe."
Èdè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ọmọ kàárọ̀ ò jí ìréré (ọmọ Yorùbá), kún fún àwọn ẹ̀wà èdè bíi òwe àti àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n míì, tó ṣeé mú yàngàn, tí a sì lè lò fún ìtónísọ́nà ọgbọ́n, òtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀, àròjinlẹ̀ àti ìwà omolúàbí láàárín ẹbí, ọ̀rẹ́ àti àwùjọ.
Lábẹ́ẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí, èdè rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ sísọ ní gbogbo ìgbà nínú ilé rẹ, àti ní ibìkan gbogbo. Nípa ṣíṣe èyí, wàá lè ní àǹfààní ìmúlò àwọn ọgbọ́n tí àwọn bàbá ńlá wa ti ń lò láti ìran dé ìran fún ìtónísọ́nà lórí àwọn ìgbésẹ̀ àti ìgbésí-ayé wọn jú.
Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èdè àti àwọn òwe Yorùbá yóò jẹ́ kí ó rọrùn fún ọ láti mọ ìgbésẹ̀ tí ó tọ́, tí ó sì yẹ ní gbogbo ìgbà. Ó jẹ́ ohun ìyanu pé kò sí bí ọ̀rọ̀ ṣe takọ́kọ́ tó, tí Yorùbá kò ní òwe tí a lè fi tú un.
"Òwe l’ẹṣin ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ l’ẹṣin òwe; tí ọ̀rọ̀ bá sọnù, òwe là fi"
Ìdí pàtàkì tí a fi gbé ètò YORÙBÁ RÓNÚ kalẹ̀ ni láti sọ gbogbo ọmọ kàárọ̀ ò jí ìréré jí; kí a lè jọ pàwọ́ pọ̀ láti gbé èdè àti àṣà Yorùbá larugẹ ní Nàìjíríà àti ní gbogbo ayé. Èdè àti àṣà wa kò gbọ́dọ̀ parun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àtọ̀húnrìn wa kò gbọ́dọ̀ kọ́ wa lẹ́rù t’ọmọ-t’ọmọ, látàrí irọ́pò èdè àti àṣà wa pẹ̀lú tiwọn!
Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè wa pẹ̀lú ìgberaga, kí a máa ṣe àkọsílẹ̀ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá pẹ̀lú àmì ohùn, kí a sì máa fi ṣe ètò àti ìfọ̀rọ̀jòmítọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára, títí èdè àti àṣà wa yóò fi di ìlú mọ̀ọ́ká; káàkiri gbogbo ayé!
Kí a lè kà ọ́ kún ọmọ Yorùbá ní tòótọ́, kí o sì lè mọ àwọn òwe tí ń sọ ènìyàn di ọlọ́gbọ́n: Darapọ̀ mọ́ wa!
Àwọn ẹ̀ka ti ètò Yorùbá Rónú pín sí ni wọ̀ny
- ÒWE:
Pa òwe kan, kí o sì ṣe àlàyé rẹ̀. - FÍ ÒWE ṢE ÀYẸ̀WÒ ÌRÒYÌN:
Fí òwe ṣe àyẹ̀wò àwọn ìròyìn àti iṣẹ́lẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè wa àti ní gbogbo ayé, kí o sì gba ọmọ Yorùbá ní amóràn lórí wọn. - FÍ ÒWE ṢE ERÉ KÚKÚRÚ:
Fí òwe ṣe eré kúkúrú láti kọ́ ọmọ Yorùbá ní ẹ̀kọ́.
Ṣé o mọ bí a ṣe ń ka àti bí a ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ Yorùbá?
Ṣé o mọ bí a ṣe ń ka àti bí a ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ Yorùbá?
Tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí o darapọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ètò tí a ṣètò rẹ̀ ní ìsàlẹ̀.